OHUN ÀRÀ TÍ Ń BẸ LÁRA ABO Ẹ̀FỌN Láti Ọwọ́ A.K.O
1. Abo ni. 2. Ọgọ́rùn-ún ojú ló ní. 3. Méjì dín láàdọ́ta ni eyín ẹnu rẹ̀. 4. Bí kòkòrò náà ṣe kéré tó ọkàn mẹ́ta lo ń bẹ nínú rẹ̀. 5. Ọ̀be mẹ́fà ló wà nínú imú rẹ̀, tí iṣẹ́ Kálukú sì yàtọ̀. 6. Apá mẹ́ta ló ní ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. 7. Nínú òkùnkùn, ẹ̀rọ kan wà fún un láti dá ara ènìyàn mọ tí yóò wá ní àwọ̀ aró. 8. Nínú ẹ̀fọn bákan náà ni àjẹsára tí kìí jẹ́ kí àwa ènìyàn ní ìmọ̀lára nígbà tí wọ́n bá ń ti ẹ̀gún bọ ara wa láti fa ẹ̀jẹ̀. 9. Wọ́n ní irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀, nítorí kìí ṣe gbobgo ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n fẹ́ràn láti máa mú. 10. Ó tún ní irinṣẹ́ kan pàtàkì láti tètè rí ẹ̀jẹ̀ fà lára. Ìwádìí kan tí ó tún ṣeni ní kàyéfì tí àwọn onímọ̀ ìgbàlódé ṣe ni pé o tún ní kòkòrò àìfojúrí tó ń ṣẹ̀mí lórí àwọn ẹ̀fọn yìí. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká gbọ́yé nígbà tÓ sọ pé "fún àpẹẹrẹ ẹ̀fọn àti nǹkan tó wà lórí rẹ̀. ...